OYE LAYE

(Lati inu owe: Eniyan laso mi)

Bi eni ba mooru,
T o si aya si,
Ma gbagbe pe:
Oye laye.

Bi asiko oginitin bade,
O nilo nkan to fi bora,

Ma gbagbe pe:
Oye laye.

Bi o ba dun loni,
O le yi biri lola,
Ma gbagbe pe:
Oye laye.

Bi eniyan ba je aso re,
A ki ju ikoko nu tori kuku ojo,
Ma gbagbe pe:
Oye laye.


Ife wa si eniyan ta ri,
La o fi won ti Olorun ti a o ri,
Ma gbagbe pe:
Oye laye.

Pele-pele laaye,
Feso logba la nso,
Ma gbagbe pe:
Oye laye.

22nd Jan, 2015

Labels: , , , , , , , ,