EWURE ILE O MO IYI ODE!

Image result for GoatEwure Ile o mo iyi ode,
Se ti ogun to ko sinu gbere ni?
Abi ti ijakadi to n ba iwun ja?
Se ti ina cambadi to gbe sori?
Abi ti iye ojo to fi n rin ninu igbe?
Ka ma ti so ibiti o je ahere re?
E je ka joro, irin ajo inu aginju.

Ti ode ba pada wale, a dupe,
Ti ode ba pa eran, ogo fun Eleduwa,
Ti ode ba lo lai fara pa, e je ki ayo,
Ti ode ba de pelu eran bintin, ka mujo,
A moye lo wa inu aginju ti o ri nkan pa!

Ise ni ode n se,
Ti ibon to fi korun ni,
Ti etutu to se ko to kori si aginju ni,
Ti ina to gbe ru ni,
Ti ada to fisi egbe ni,
Ti ede enu re ni,
Ti iwun to ba ja ni,
Ti a na ni otutu ni,
Ode n gbiyanju!

Bowo ode de,
Bi ode,
E yin lawo,
Omo ode kan o si,
Akin ni a ma n ba ode,
Ode gboya,
Ode laya,
Ode kiya!

Amosa,
Ewure ma koja aiye re,
Awon miran n so ode o!
Won fe ko woo do awon o!
Won fe fiyi re han,
Rora toju ode yii o!
Ki gbogbo aiye lemo wipe,
Ewure ile ti n mo iyi Ode!

12:50pm, 14th August, 2012

Labels: , , , , , , , , ,