TENÍ BÉGI LÓJÙ, IGI Á RÚWÉ

IGI Á RÚWÉ


Igi á rúwé,

Dandan ni!

Igi le ge!

E o fà á tu!



Té ò bá tíì rí gbòngbò fà tu!

Èmi ò pin!

Ìse ò tán!

Èyí té e se ò sòro!

Esè méjì lo seyin!

A fi méjì tèsìwájú!



Aseni se ara rè!

Ó rò pé èmi lòun se!

Ohun a fi orí se ló tójó!

Ohun a fi ipá mú ni bàjé!

Tèsíwájú, owó pálábá re féè ségi!



Ò pàpà paradà!

Igi á rúwé!

Teni bégi ló jù.


Láti inú òwe:, TENÍ BÉGI LÓJÙ, IGI Á RÚWÉ

Literally meaning: the tree would flourish again, the person who did the lumbering bears the brunt more



Labels: , , , , , , , , ,